Lo Kede Ayo Na Lyrics
- Genre:Gospel
- Year of Release:2023
Lyrics
Lo kede ayo na fun gbogbo aiye
P'Omo Olorun segun iku
Fi tiyin-tiyin pel'ayo rohin na
Emi Mimo to gunwa
Oba mi de
Asegun mi de
Ogo Ola at'agbara at'ipa
F'Odaguntan to gunwa
Iyin Jesu l'awon Angeli nke
T'o wa ra araiye pada
Okan soso ajanaku ni Jesu
T'o m'aiye pelu orun
O de!
Oba mi de
Asegun mi de
Ogo Ola at'agbara at'ipa
F'Odaguntan to gunwa
Bi orile-ede enia dudu
Ati ka wa si eweko
Sugbon awa ni Baba kan l'oke
T'o mo pe 'se Re ni wa!
O de!
Oba mi de
Asegun mi de
Ogo Ola at'agbara at'ipa
F'Odaguntan to gunwa
Ojo nla kan ma mbo
T'Olusiro y'o de
Gbogbo eniyan y'o ri
Aye yio wariri
Igbagbo re ha da
Wo ti ko m'Olorun
T'o f'eda se igbekele
T'o f' Oluwa sile
Ayo pupo yio wa
L'okan ti Jesu ngbe
Ti nwon ti ko aiye sile
T'o gba Emi Mimo